YORUBA (NIGERIA)

Sunnah Reloaded

Awon Sunnah ti Won ti gbe Ju sile

Gbogbo ope ti Olohun Oba Aleke Ola ni, Adupe fun, Awa Iranwo re, Awa afi orijin re, Awa iso pelu Olohun nibi royi royi emi wa, ati awon aburu ise owo wa, eniti Olohun bafimo ona kosi eninaa ti ole sini ona, eniti obasi si ni ona kosi eninaa ti olefi mo ona.

Olohun Oba aleke ola ohun bawa soro ninu Alquran Alaponle: (Eyin oni igbagbo ododo eberu Olohun niti papa iberu ema seku ayafi ki eje musulumi ododo). suratul Al Imuroon: ogorun le meji.

Dajudaju oro ti oni oore ju ni oro Olohun Oba aleke ola, oju ona ti oloore ju  naani oju ona Anabi muhammed (ki ike ati ige olohun ma ba), Gbogbo adada sile adada sile ni yi o maa je, gbogbo adada sile ona anuni, gbogbo ona anu ina ni iseri si won.

Leyin Igbana: Kini ojuponna Anabi?

Ojuponna Anabi ni: Gbogbo unkan ti afiti si odo Onise unla Anabi wa muhammed (ki ike ati ige olohun ma ba), ninu gbolohun, ise, fifi rinle abi iroyin.

Pataki ojuponna Anabi.

Papa won gbawa lati odo Anabi (ki ike ati ige Olohun maa baa)- osobayi wipe ( mofi sile fun yin unkan tojepe ti eba gbamu sinsin leyin mi e ko ni sonu, ohun naani Al quran ati ojuponna mi).

Anabi (ki ike ati ige Olohun maa ba) tun so bayi pe: (Odi owo yin ojuponna mi ati ojuponna awon Arole eni ire awon olufini mona ni eyin mi…).

Ojuponna Anabi (ki ike ati ige Olohun maa ba) ni oju ona losi ogba idera.

Imam molik sope: (Ojuponna Anabi bi oko oju omi Nuhu ni, eniti oba gun yio la, eniti oba yapa re yio teri).

Dhu Nuun Almosriyi so wipe: (Ninu apere ife Olohun oba aleke ola ohun naa tite le Ojuponna Anabi ( ki ike ati ige Olohun maaba nibi awon iwa re ati awon isee re ati awon asee re ati ojuponna re).

Olohun oba aleke ola so ninu Al quran Alaponle :(So fun won pe ti obajepe lo tito ni eba ni ife Olohun, e tele mi, Olohun yoo ni ife yin, yi o si se aforijin awon ese yin fun yin, Olohun oba alaforijin oni ike sini) Suratul Al Imurohnu: Ikokan le ni ogbon.

Alfa ojogbon Hasan AlBasory Sope: (Apere ife won sii ni titele ojuponna ojise Olohun ki ike ati ige Olohun maa ba.

Daju Daju aaye olu gbagbo ododo won o maa won pelu titele ojise Olohun (ki ike ati ige Olohun maa ba), gbogbo bi  titele ojuponna ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun maa ba) base poto, bee naa ni yio seje eni agbega ati eni abiyi to.

Nini akole okan ojuponna ojise Olohun ahun faani ti opo ni owa ni ibe, Ninu re:

1- Yio sun wadi okan ninu eniti oba aleke ola ni ife si.

2- Yio pe adinku ti obawa nibi ise oran yan.

3- Yio sowa kuro lati bosi inu adada sile.

4- Gbigbe awon Aami esin Olohun tobi.

Paapa Inira tiwa, awon fitina sitipo ni oni, Ni ipase gbigbe jusile ti opolopo musulumi ti gbe ojupona ojise Olohun (ki ike ati ige Olohun maa ba) jusile, ati titele awon abori kunkun ati awon pokii nibi jije, mimu, wiwo, ati bee bee lo, titi ti  opolopo ojuponna ojise (ki ike ati ige Olohun maa ba) waa fi di ohun igbagbe.

Taani yio wagbe awon ojuponna ti wonti gbagbe yi dide pada, ti yio si da pada si bi oti wa tele?

Ojise (ki ike ati ige Olohun maa ba) so wipe: (Eniti obaji ojuponna kan ninu awon ojuponna mi ti awon eniyan wafihun se ise se, yio ni iru lada eniti ofi se ise se, ti kosi ni din unkankan ku ninu  laada won) (Ibn Moojah).

Awon ojuponna mejo kan niyi ti won ti gbe jusile, ti won sifi ese mule la ti odo ojise (ki ike ati ige Olohun maa baa):

 

1- Gbigbon idoti ohunje ti oba jabo jusile ki asi je:

Lati odo Jaabir (ki Olohun yonu si): Ojise (ki ike ati ige Olohun maa ba) towa nika si lila awon omonika ati abo, owa sope: (Daju daju e ko mo eyiti alubarika wani ibe). (Muslim lo gba wa), Ninu egba wa mi: (Ti okele enikan ninu yin ba jabo, ki o ya muu, ki o si gbon suta ti o ba wa lara re nu, ki o si jee, ki o ma fi sile fun Esu (Shaytoon), ki o si ma ma nu owo re pelu inu-idoti titi ti yoo fi la awon omo ika re, toripe ko mo ibi eyi ti Alubarika wa ninu ounje re). (Muslim lo gba wa).

 

2- Opolopo wiwa aforijin ni ibujoko:

Lati odo Abdullahi omo umor (Ki Olohun yonu si awon mejeeji) O so wipe: Ama n ka fun Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), ni ibujoko kan Ogorun: (robbi ig’rif lii, wa tub alayyah, Innaka Anta tawwaabu roheem). Abu daud ati Tir’midhi lo gba wa, Al’baani si fi ese re mule.

 

3- Fifi ori kanle fun idupe ti idunnu ba sele, ati ibanuje ba kuro:

Imamu bagowiy so ninu (Sharhu sunnah): Fifi ori kan le fun idupe Ojuponna Ojise ni, ti Oore ti anreti ba sele, abi ti adanwo ti anre wa didopin re ba dopin.

Imam ibn qoyyim so wipe: Ninu ilana ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), ati ilana awon ti won ba logba ni fifi orikan le fun idupe ti oore otun ba sele, abi ibanuje ba dopin.

 

4- Yiyan rakah meji lasiko tutuba kuro nibi ese:

Lati odo Abubakri olododo (ki Olohun yonu si: Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), So wipe: (Ko si enikankan ti o da ese kan, ti o wa se imora, ti o wayan nafila (ninu egba wa kan: rakah mejeji), ti o wa wa aforijin Olohun, Afi ki Olohun fi ori jinn). Abu daud ati Tir’midhi lo gba wa, Al’baani si fi ese re mule.

 

5- Ninifesi kiko Asotele:

Tati odo omo umor (ki Olohun yonu si awon mejeeji): Dajudaju ojise olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), so wipe: (Kii se eto musulumi  ti oni inkan ti o fe so asotele si, ki o wa sun oorun ale meji (ninu egbawa kan: Ale meta), aya fi ki asotele re wa ni kiko lodo re). Won panu po lori egbawa yi.

Imamu Naafiu so wipe: Mo gbo ti Abdullahi omo umor n sowipe: Ale kan kan ko ko ja fun mi lati igbati moti gbo ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), to so bayen, Ayafi ki Akosile mi wa ni kiko lodo mi.

 

6- Mimo fi owo sile ti aba bowo titi ti eni keji fi ma fi sile:

Lati odo Anas (ki Olohun yonu si) so wipe: Ti ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), ba bo enikan lowo, ko ni fi owo re sile, titi ti eni to bo lowo fi ma fi owo ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), sile. Albaani fi ese re mule.

 

7- Mima fi ara kan ojo ti o ban ro:

Lati odo Anas (ki Olohun yonu si) so wipe: Ojo pawa pelu ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), wa si aso re, titi ti ojo fi kan ara re, a wa bere wipe: iwo ojise Olohun, ki lode ti o fi se bayi?, o wa so wipe: (Tori pe o sese kuro lodo Olohun oba ni). (Muslim lo gba wa). Imamu Nawawi so ninu alaye re: (O wa ninu egbawa yi eri fun oro awon eeyan wa wipe: Won fe ki ama si ara wa yatosi ihoho nigbati ojo ba bere si n ro).

 

8- Sise (Allahu Ak’bar) ati (Sub’hanallahi) nigbati aba ri nkan eemo abi inkan ti okan ko:

Lati odo Abu hurayra (ki Olohun yonu si) so wipe: Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), pade re ni oju ona kan ni medinah, ti o si ni Janaba lara, oju wa gba ti, o wa lo we iwe oranyan, Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba),wa se abewo re, ni igba tode o so wipe: (Ibo ni o wa tele, ire Abu Hurayrah?), Abu hurayra so wipe: Ire Ojise Olohun, O pade mi, Mo si ni Janaba lara, Mo wa korira kin joko pelu re titi ti ma fi we iwe oranyan, Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba),so wipe: (Sub’hanallahi! Daju daju Musulumi ko kin se elegbin) (won panu po lori egbewa yi).

 

Lati odo Baba saheed Al-khud’riy (Ki Olohun yonu si) so wipe: Ojise Olohun (ki ike ati ige olohun ma ba), so wipe: (Dajudaju, Emi n ran kan ki e je Ida merin ara Al-jannah), Awa gbe Olohun tobi (Allahu Ak’bar), o tun wa so wipe: (Ida meta ara Al-jannah), Awa gbe Olohun tobi (Allahu Ak’bar), o tun wa so wipe: (Ida meji ara Al-jannah), Awa gbe Olohun tobi (Allahu Ak’bar). (won panu po lori egbewa yi).

 

BROUGHT TO YOU BY:

THE HIDDEN PRESTIGE